Native Bible

Matthew 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.”

Matthew 2:13 in English

Matthew 2:13 · Berean Standard Bible

When the Magi had gone, an angel of the Lord appeared to Joseph in a dream. “Get up!” he said. “Take the Child and His mother and flee to Egypt. Stay there until I tell you, for Herod is going to search for the Child to kill Him.”

Context

11Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Maria ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ìṣúra wọn, wọ́n sì ta Jesu lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjìá. 12Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Herodu lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn. 13Nígbà tí wọn ti lọ, angẹli Olúwa fi ara hàn Josẹfu ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sálọ sí Ejibiti. Dúró níbẹ̀ títí tí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Herodu yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ ọwọ́ náà.” 14Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Ejibiti, 15ó sì wà níbẹ̀ títí tí Herodu fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé, “Mo pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.