Native Bible

Matthew 18:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá.

Matthew 18:30 in English

Matthew 18:30 · Berean Standard Bible

But he refused. Instead, he went and had the man thrown into prison until he could pay his debt.

Context

28“Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘San gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’ 29“Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’ 30“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. 32“Nígbà tí olúwa rẹ̀ pè ọmọ ọ̀dọ̀ náà wọlé, ó wí fún un pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, níhìn-ín ni mo ti dárí gbogbo gbèsè rẹ jì ọ́ nítorí tí ìwọ bẹ̀ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.