Matiu 18:29
Matthew 18:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’
Matthew 18:29 in English
Matthew 18:29 · Berean Standard Bible
So his fellow servant fell down and begged him, ‘Have patience with me, and I will pay you back.’
Context
27Nígbà náà, ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì ṣàánú fún un. Ó tú u sílẹ̀, ó sì fi gbèsè náà jì í. 28“Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti jáde lọ, ó rí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ tí ó jẹ ẹ́ ní ọgọ́rùn-ún owó idẹ, ó gbé ọwọ́ lé e, ó fún un ní ọrùn, ó wí pé, ‘San gbèsè tí o jẹ mí lójú ẹsẹ̀.’ 29“Ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ náà sì wólẹ̀ lórí eékún níwájú rẹ̀, ò ń bẹ̀ ẹ́ pé, ‘Mú sùúrù fún mi, èmi yóò sì san án fún ọ.’ 30“Ṣùgbọ́n òun kọ̀ fún un. Ó pàṣẹ kí a mú ọkùnrin náà, kí a sì jù ú sínú túbú títí tí yóò fi san gbèsè náà tán pátápátá. 31Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, inú bí wọn gidigidi, wọ́n lọ láti lọ sọ fún olúwa wọn, gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.