Native Bible

Matthew 14:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.”

Matthew 14:18 in English

Matthew 14:18 · Berean Standard Bible

“Bring them here to Me,” Jesus said.

Context

16Ṣùgbọ́n Jesu fèsì pé, “Kò nílò kí wọ́n lọ kúrò. Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” 17Wọ́n sì dalóhùn pé, “Àwa kò ní ju ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì lọ níhìn-ín.” 18Ó wí pé, “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín yìí.” 19Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn. 20Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. Lẹ́yìn náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kó àjẹkù jọ, ó kún agbọ̀n méjìlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.