Native Bible

Matthew 13:53 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ti Jesu ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò.

Matthew 13:53 in English

Matthew 13:53 · Berean Standard Bible

When Jesus had finished these parables, He withdrew from that place.

Context

51Jesu bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.” Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.” 52Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn ní ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.” 53Lẹ́yìn ti Jesu ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò. 54Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Sinagọgu, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá? 55Kì í ha ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ ha kọ́ ni à ń pè ní Maria bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jakọbu, Josẹfu, Simoni àti Judasi bí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.