Matiu 13:3
Matthew 13:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé, “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀.
Matthew 13:3 in English
Matthew 13:3 · Berean Standard Bible
And He told them many things in parables, saying, “A farmer went out to sow his seed.
Context
1Ní ọjọ́ kan náà, Jesu kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí Òkun. 2Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí Òkun. 3Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé, “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀. 4Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. 5Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.