Matiu 13:22
Matthew 13:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀.
Matthew 13:22 in English
Matthew 13:22 · Berean Standard Bible
The seed sown among the thorns is the one who hears the word, but the worries of this life and the deceitfulness of wealth choke the word, and it becomes unfruitful.
Context
20Ẹni tí ó sì gba irúgbìn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ orí àpáta, ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, lọ́gán, ó sì fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà. 21Ṣùgbọ́n nítorí kò ní gbòǹgbò, ó wà fún ìgbà díẹ̀; nígbà tí wàhálà àti inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà ní ojú kan náà yóò sì kọsẹ̀. 22Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. 23Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.” 24Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.