Native Bible

Matthew 13:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀,

Matthew 13:24 in English

Matthew 13:24 · Berean Standard Bible

Jesus put before them another parable: “The kingdom of heaven is like a man who sowed good seed in his field.

Context

22Ẹni tí ó si gba irúgbìn tí ó bọ́ sí àárín ẹ̀gún ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àwọn àníyàn ayé yìí, ìtànjẹ, ọrọ̀ sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ọ̀rọ̀ náà kò so èso nínú rẹ̀. 23Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba irúgbìn tí ó bọ́ sí orí ilẹ̀ rere ni ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì yé e; òun sì so èso òmíràn ọgọ́rọ̀ọ̀rùn, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n.” 24Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí àgbẹ̀ kan tí ó gbin irúgbìn rere sí oko rẹ̀, 25ṣùgbọ́n ní òru ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá sí oko náà ó sì gbin èpò sáàrín alikama, ó sì bá tirẹ̀ lọ. 26Nígbà tí alikama náà bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà, tí ó sì so èso, nígbà náà ni èpò náà fi ara hàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.