Native Bible

Matthew 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?”

Matthew 11:3 in English

Matthew 11:3 · Berean Standard Bible

to ask Him, “Are You the One who was to come, or should we look for someone else?”

Context

1Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo. 2Nígbà tí Johanu gbọ́ ohun tí Kristi ṣe nínú ẹ̀wọ̀n, ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ 3láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣe ìwọ ni ẹni tó ń bọ̀ wá tàbí kí a máa retí ẹlòmíràn?” 4Jesu dáhùn ó wí pé, “Ẹ padà lọ, ẹ sì sọ fún Johanu ohun tí ẹ̀yin gbọ́, àti èyí tí ẹ̀yin rí. 5Àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn amúnkùn ún rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ wọn, àwọn adití ń gbọ́rọ̀, a ń jí àwọn òkú dìde, a sì ń wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.