Native Bible

Luke 8:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba.

Luke 8:17 in English

Luke 8:17 · Berean Standard Bible

For there is nothing hidden that will not be disclosed, and nothing concealed that will not be made known and brought to light.

Context

15Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso. 16“Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀. 17Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba. 18Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin máa kíyèsára bí ẹ̀yin ti ń gbọ́: nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní, lọ́wọ́ rẹ̀ ni a ó sì gba èyí tí ó ṣe bí òun ní.” 19Nígbà náà ní ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn kò sì lè súnmọ́ ọn nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.