Native Bible

Luke 8:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

Luke 8:15 in English

Luke 8:15 · Berean Standard Bible

But the seeds on good soil are those with a noble and good heart, who hear the word, cling to it, and by persevering produce a crop.

Context

13Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn. 14Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó. 15Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso. 16“Kò sí ẹnikẹ́ni, nígbà tí ó bá tán fìtílà tan, tí yóò fi ohun èlò bò ó mọ́lẹ̀, tàbí tí yóò gbé e sábẹ́ àkéte; bí kò ṣe kí ó gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà, kí àwọn tí ń wọ ilé lè rí ìmọ́lẹ̀. 17Nítorí kò sí ohun tí ó fi ara sin, tí a kì yóò fihàn, tàbí ohun tí a fi pamọ́, ti a kì yóò sì mọ̀ kí ó sì yọ sí gbangba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.