Native Bible

Luke 8:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.

Luke 8:13 in English

Luke 8:13 · Berean Standard Bible

The seeds on rocky ground are those who hear the word and receive it with joy, but they have no root. They believe for a season, but in the time of testing, they fall away.

Context

11“Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 12Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò ní ọkàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là. 13Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sá à díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn. 14Àwọn tí ó bọ́ sínú ẹ̀gún ni àwọn, tí wọ́n gbọ́ tán, wọ́n ti n lọ, wọn a sì fi ìtọ́jú àti ọrọ̀ àti ìrora ayé fún un pa, wọn kò sì lè so èso àsogbó. 15Ṣùgbọ́n ti ilẹ̀ rere ni àwọn tí wọ́n fi ọkàn òtítọ́ àti rere gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n dìímú ṣinṣin, wọ́n sì fi sùúrù so èso.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.