Native Bible

Luke 22:65 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.

Luke 22:65 in English

Luke 22:65 · Berean Standard Bible

And they said many other blasphemous things against Him.

Context

63Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà. 66Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!” Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.