Native Bible

Luke 22:43 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú.

Luke 22:43 in English

Luke 22:43 · Berean Standard Bible

Then an angel from heaven appeared to Him and strengthened Him.

Context

41Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà. 42Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mu ago yìí kúrò lọ́dọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.” 43Angẹli kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú. 44Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀. 45Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.