Native Bible

Luke 20:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

Luke 20:18 in English

Luke 20:18 · Berean Standard Bible

Everyone who falls on this stone will be broken to pieces, but he on whom it falls will be crushed.”

Context

16Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!” 17Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’? 18Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.” 19Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn. 20Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.