Luku 19:38
Luke 19:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”
Luke 19:38 in English
Luke 19:38 · Berean Standard Bible
“Blessed is the King who comes in the name of the Lord!”* “Peace in heaven and glory in the highest!”*
Context
36Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. 37Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí, 38wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”
“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!” 39Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.” 40Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.