Lefitiku 9:11
Leviticus 9:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.
Leviticus 9:11 in English
Leviticus 9:11 · Berean Standard Bible
But he burned up the flesh and the hide outside the camp.
Context
9Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 10Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó. 12Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 13Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.