Lefitiku 6:14
Leviticus 6:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú Olúwa níwájú pẹpẹ.
Leviticus 6:14 in English
Leviticus 6:14 · Berean Standard Bible
Now this is the law of the grain offering: Aaron’s sons shall present it before the LORD in front of the altar.
Context
12Iná tó wà lórí pẹpẹ gbọdọ̀ máa jó, kò gbọdọ̀ kú, ní àràárọ̀ ni kí àlùfáà máa to igi si, kí ó sì to ẹbọ sísun sórí iná, kí ó sì máa sun ọ̀rá ẹran ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀. 13Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú. 14“ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú Olúwa níwájú pẹpẹ. 15Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa. 16Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.