Native Bible

Leviticus 6:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.

Leviticus 6:15 in English

Leviticus 6:15 · Berean Standard Bible

The priest is to remove a handful of fine flour and olive oil, together with all the frankincense from the grain offering, and burn the memorial portion on the altar as a pleasing aroma to the LORD.

Context

13Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú. 14“ ‘Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Aaroni gbé ẹbọ sísun náà wá síwájú Olúwa níwájú pẹpẹ. 15Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa. 16Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò jẹ ìyókù ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ láìsí máa wú máa wú ohun tí ń mú àkàrà wú nínú rẹ̀ ní ibi mímọ́, ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé ni kí wọn ó ti jẹ ẹ́. 17Ẹ má ṣe ṣè é pẹ̀lú ìwúkàrà. Èmi ti fún àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn nínú ẹbọ tí a fi iná sun sí mi. Ó jẹ́ mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi náà ṣe jẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.