Native Bible

Leviticus 5:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni.

Leviticus 5:15 in English

Leviticus 5:15 · Berean Standard Bible

“If someone acts unfaithfully and sins unintentionally against any of the LORD’s holy things, he must bring his guilt offering to the LORD: an unblemished ram from the flock, of proper value * in silver shekels according to the sanctuary shekel;* it is a guilt offering.

Context

13Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ” 14Olúwa sọ fún Mose pé, 15“Nígbà tí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ ìrékọjá tí ó sì ṣe láìmọ̀ ní ti àwọn ohun mímọ́ Olúwa, kí ó mú àgbò láti inú agbo ẹran wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn, àgbò tí kò lábùkù tí ó sì níye lórí gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́. Ẹbọ ẹ̀bi ni. 16Kí ó ṣe àtúnṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ nínú ti àwọn ohun mímọ́, kí ó sì fi ìdámárùn-ún kún iye rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ fún àlùfáà. Àlùfáà yóò sì fi àgbò ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ṣe ètùtù fún, a ó sì dáríjì í. 17“Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun tí kó yẹ ko ṣe sí ọ̀kan nínú òfin Olúwa, bí kò tilẹ̀ mọ̀, ó jẹ̀bi, yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.