Native Bible

Leviticus 23:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan).

Leviticus 23:13 in English

Leviticus 23:13 · Berean Standard Bible

along with its grain offering of two-tenths of an ephah of fine flour * mixed with oil—an offering made by fire to the LORD, a pleasing aroma—and its drink offering of a quarter hin of wine.*

Context

11Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi. 12Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 13Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan). 14Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 15“ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú ìdì ọkà fífì wá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.