Native Bible

Leviticus 23:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

Leviticus 23:14 in English

Leviticus 23:14 · Berean Standard Bible

You must not eat any bread or roasted or new grain until the very day you have brought this offering to your God. This is to be a permanent statute for the generations to come, wherever you live.

Context

12Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 13Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan). 14Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé. 15“ ‘Ẹ ka ọ̀sẹ̀ méje gbangba, láti ọjọ́ kejì ọjọ́ ìsinmi, àní ọjọ́ tí ẹ mú ìdì ọkà fífì wá. 16Ẹ ka àádọ́ta ọjọ́ títí dé ọjọ́ kejì ọ̀sẹ̀ méjèèje, kí ẹ sì mú ọrẹ ọkà tuntun wá fún Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.