Native Bible

Leviticus 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.

Leviticus 21:8 in English

Leviticus 21:8 · Berean Standard Bible

You are to regard him as holy, since he presents the food of your God. He shall be holy to you, because I the LORD am holy—I who set you apart.

Context

6Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́. 7“ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn. 8Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́. 9“ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún. 10“ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi àmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.