Lefitiku 16:24
Leviticus 16:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.
Leviticus 16:24 in English
Leviticus 16:24 · Berean Standard Bible
He is to bathe himself with water in a holy place and put on his own clothes. Then he must go out and sacrifice his burnt offering and the people’s burnt offering to make atonement for himself and for the people.
Context
22Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù. 23“Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀. 24Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn. 25Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ. 26“Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.