Lefitiku 16:22
Leviticus 16:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.
Leviticus 16:22 in English
Leviticus 16:22 · Berean Standard Bible
The goat will carry on itself all their iniquities into a solitary place, and the man will release it into the wilderness.
Context
20“Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti Ibi Mímọ́ Jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ, òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí. Gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. 22Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù. 23“Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí Ibi Mímọ́ Jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀. 24Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan, yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú, yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.