Native Bible

Leviticus 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.

Leviticus 1:9 in English

Leviticus 1:9 · Berean Standard Bible

The entrails and legs must be washed with water, and the priest shall burn all of it on the altar as a burnt offering, an offering made by fire, a pleasing aroma to the LORD.

Context

7Àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà. 8Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.