Lefitiku 1:10
Leviticus 1:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù,
Leviticus 1:10 in English
Leviticus 1:10 · Berean Standard Bible
If, however, one’s offering is a burnt offering from the flock—from the sheep or goats—he is to present an unblemished male.
Context
8Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà yóò tó ègé ẹran náà, pẹ̀lú orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 9Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká. 12Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.