Lefitiku 1:12
Leviticus 1:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ.
Leviticus 1:12 in English
Leviticus 1:12 · Berean Standard Bible
He is to cut the animal into pieces, and the priest shall arrange them, including the head and fat, atop the burning wood that is on the altar.
Context
10“ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú ọ̀wọ́ ẹran, láti ara àwọn àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tàbí àgùntàn, kí ó mú akọ tí kò lábùkù, 11kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká. 12Kí ó gé e sí wẹ́wẹ́, kí àlùfáà sì to ègé ẹran náà; orí àti ọ̀rá rẹ̀ sí orí igi tó ń jó lórí pẹpẹ. 13Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa. 14“ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Olúwa, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.