Native Bible

Lamentations 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

Lamentations 4:9 in English

Lamentations 4:9 · Berean Standard Bible

Those slain by the sword are better off than those who die of hunger, who waste away, pierced with pain because the fields lack produce.

Context

7Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì, wọ́n sì funfun ju wàrà lọ wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa, ìrísí wọn dàbí safire. 8Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú; wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó. Ara wọn hun mọ́ egungun; ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ. 9Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn ju àwọn tí ìyàn pa; tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò fún àìní oúnjẹ láti inú pápá. 10Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ tí ó di oúnjẹ fún wọn nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run. 11Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀; ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde. Ó da iná ní Sioni tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.