Ẹkún Jeremiah 4:12
Lamentations 4:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́, tàbí àwọn ènìyàn ayé, wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ odi ìlú Jerusalẹmu.
Lamentations 4:12 in English
Lamentations 4:12 · Berean Standard Bible
The kings of the earth did not believe, nor any people of the world, that an enemy or a foe could enter the gates of Jerusalem.
Context
10Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú
ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ
tí ó di oúnjẹ fún wọn
nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run. 11Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;
ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.
Ó da iná ní Sioni
tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run. 12Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,
tàbí àwọn ènìyàn ayé,
wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ
odi ìlú Jerusalẹmu. 13Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì
àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,
tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo
sílẹ̀ láàrín rẹ̀. 14Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó
bí ọkùnrin tí ó fọ́jú.
Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n
tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.