Ẹkún Jeremiah 2:4
Lamentations 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra. Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.
Lamentations 2:4 in English
Lamentations 2:4 · Berean Standard Bible
He has bent His bow like an enemy; His right hand is positioned. Like a foe He has killed all who were pleasing to the eye; He has poured out His wrath like fire on the tent of the Daughter of Zion.
Context
2Láìní àánú ni Olúwa gbé
ibùgbé Jakọbu mì;
nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó
ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀.
Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin
lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀. 3Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké
gbogbo ìwo Israẹli.
Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò
nígbà tí àwọn ọ̀tá dé.
Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná
ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni. 4Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra.
Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun
ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná
sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni. 5Olúwa dàbí ọ̀tá;
ó gbé Israẹli mì.
Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì
ó pa ibi gíga rẹ̀ run.
Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀
fún àwọn ọmọbìnrin Juda. 6Ó mú ìparun bá ibi mímọ́,
ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run.
Olúwa ti mú Sioni gbàgbé
àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn;
nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run
ọba àti olórí àlùfáà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.