Ẹkún Jeremiah 2:12
Lamentations 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn.
Lamentations 2:12 in English
Lamentations 2:12 · Berean Standard Bible
They cry out to their mothers: “Where is the grain and wine?” as they faint like the wounded in the streets of the city, as their lives fade away in the arms of their mothers.
Context
10Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni
jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;
wọ́n da eruku sí orí wọn
wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu
ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀. 11Ojú mi kọ̀ láti sọkún,
mo ń jẹ ìrora nínú mi,
mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀
nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,
nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú
ní òpópó ìlú. 12Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,
“Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó
bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe
ní àwọn òpópónà ìlú,
bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò
láti ọwọ́ ìyá wọn. 13Kí ni mo le sọ fún ọ?
Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,
ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,
kí n lè tù ọ́ nínú,
ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.
Ta ni yóò wò ọ́ sàn? 14Ìran àwọn wòlíì rẹ
jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.