Native Bible

Lamentations 2:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

Lamentations 2:13 in English

Lamentations 2:13 · Berean Standard Bible

What can I say for you? To what can I compare you, O Daughter of Jerusalem? To what can I liken you, that I may console you, O Virgin Daughter of Zion? For your wound is as deep as the sea. Who can ever heal you?

Context

11Ojú mi kọ̀ láti sọkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú. 12Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn. 13Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn? 14Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà. 15Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.