Ẹkún Jeremiah 1:4
Lamentations 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀, nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn. Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro, àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn, àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú, òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.
Lamentations 1:4 in English
Lamentations 1:4 · Berean Standard Bible
The roads to Zion mourn, because no one comes to her appointed feasts. All her gates are deserted; her priests groan, her maidens grieve, and she herself is bitter with anguish.
Context
2Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò
pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.
Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀
wọ́n ti di alátakò rẹ̀. 3Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,
Juda lọ sí àjò
Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.
Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́
ibi tí kò ti le sá àsálà. 4Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn.
Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro,
àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,
àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú,
òun gan an wà ní ọkàn kíkorò. 5Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,
nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,
Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́
nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,
ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá. 6Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé
kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.
Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín
tí kò rí ewé tútù jẹ;
nínú àárẹ̀ wọ́n sáré
níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.