Joṣua 8:22
Joshua 8:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọmọ-ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Israẹli ní ìhà méjèèjì. Israẹli sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó sálọ nínú wọn.
Joshua 8:22 in English
Joshua 8:22 · Berean Standard Bible
Meanwhile, those in the ambush came out of the city against them, and the men of Ai were trapped between the Israelite forces on both sides. So Israel struck them down until no survivor or fugitive remained.
Context
20Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn. 21Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai. 22Àwọn ọmọ-ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Israẹli ní ìhà méjèèjì. Israẹli sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó sálọ nínú wọn. 23Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Ai láààyè, wọ́n sì mu un tọ Joṣua wá. 24Nígbà tí Israẹli parí pípa gbogbo àwọn ìlú Ai ní pápá àti ní aginjù ní ibi tí wọ́n ti lépa wọn lọ, tí gbogbo wọ́n sì ti ojú idà ṣubú, tí a fi pa gbogbo wọn tan, gbogbo àwọn Israẹli sì padà sí Ai, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.