Joṣua 8:21
Joshua 8:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai.
Joshua 8:21 in English
Joshua 8:21 · Berean Standard Bible
When Joshua and all Israel saw that the men in ambush had captured the city and that smoke was rising from it, they turned around and struck down the men of Ai.
Context
19Bí ó ti ṣe èyí tán, àwọn ọkùnrin tí ó ba sì dìde kánkán kúrò ní ipò wọn, wọ́n sáré síwájú. Wọn wọ ìlú náà, wọ́n gbà á, wọ́n sì yára ti iná bọ̀ ọ́. 20Àwọn ọkùnrin Ai bojú wo ẹ̀yìn, wọ́n rí èéfín ìlú náà ń gòkè lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n wọn kò rí, ààyè láti sá àsálà lọ sí ibìkan kan, nítorí tí àwọn ará Israẹli tí wọ́n tí ń sálọ sí aginjù ti yípadà sí àwọn tí ń lépa wọn. 21Nígbà tí Joṣua àti gbogbo àwọn ará Israẹli rí i pé àwọn tí ó bá ti gba ìlú náà, tí èéfín ìlú náà sì ń gòkè, wọ́n yí padà wọ́n sì kọlu àwọn ọkùnrin Ai. 22Àwọn ọmọ-ogun tí ó ba náà sì yípadà sí wọn láti inú ìlú náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wà ní agbede-méjì àwọn ará Israẹli ní ìhà méjèèjì. Israẹli sì pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì jẹ́ kí ọ̀kan kí ó yè tàbí kí ó sálọ nínú wọn. 23Ṣùgbọ́n wọ́n mú ọba Ai láààyè, wọ́n sì mu un tọ Joṣua wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.