Joṣua 4:23
Joshua 4:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.
Joshua 4:23 in English
Joshua 4:23 · Berean Standard Bible
For the LORD your God dried up the waters of the Jordan before you until you had crossed over, just as He did to the Red Sea,* which He dried up before us until we had crossed over.
Context
21Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 22Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’ 23Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá. 24Ó ṣe èyí kí gbogbo ayé lè mọ̀ pé ọwọ́ Olúwa ní agbára, àti kí ẹ̀yin kí ó lè máa bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín ní ìgbà gbogbo.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.