Native Bible

Joshua 4:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

Joshua 4:21 in English

Joshua 4:21 · Berean Standard Bible

Then Joshua said to the Israelites, “In the future, when your children ask their fathers, ‘What is the meaning of these stones?’

Context

19Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko. 20Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali. 21Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’ 22Nígbà náà ni ẹ ó jẹ́ kí àwọn ọmọ yín mọ̀ pé, ‘Israẹli rékọjá odò Jordani ní orí ilẹ̀ gbígbẹ.’ 23Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín mú Jordani gbẹ ní iwájú u yín títí ẹ̀yin fi kọjá. Olúwa Ọlọ́run yín ti ṣe sí Jordani gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Òkun Pupa, nígbà tí ó mú un gbẹ ní iwájú wa títí àwa fi kọjá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.