Native Bible

Joshua 4:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko.

Joshua 4:19 in English

Joshua 4:19 · Berean Standard Bible

On the tenth day of the first month the people went up from the Jordan and camped at Gilgal on the eastern border of Jericho.

Context

17Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé, “Ẹ jáde kúrò nínú odò Jordani.” 18Àwọn àlùfáà náà jáde láti inú odò pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa ni orí wọn. Bí wọ́n ti fi ẹsẹ̀ ẹ wọn tẹ orí ilẹ̀ gbígbẹ ni omi Jordani náà padà sí ààyè e rẹ̀, o sì kún wọ bèbè bí i ti àtẹ̀yìnwá. 19Ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kìn-ín-ní àwọn ènìyàn náà lọ láti Jordani, wọ́n sì dúró ní Gilgali ní ìlà-oòrùn Jeriko. 20Joṣua sì to àwọn òkúta méjìlá tí wọ́n mú jáde ní Jordani jọ ní Gilgali. 21Ó sì sọ fún àwọn ará Israẹli, “Ní ọjọ́ iwájú nígbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè ní ọwọ́ baba wọn pé, ‘Kín ni òkúta wọ̀nyí dúró fún?’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.