Native Bible

Joshua 24:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.”

Joshua 24:21 in English

Joshua 24:21 · Berean Standard Bible

“No!” replied the people. “We will serve the LORD!”

Context

19Joṣua sì wí fún àwọn ènìyàn náà, pé, “Ẹ̀yin kò le sin Olúwa, nítorí Ọlọ́run mímọ́ ni òun; Ọlọ́run owú ni òun, kì yóò dárí ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. 20Bí ẹ bá kọ Olúwa tí ẹ sì sin òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn òun yóò padà yóò sì mú ibi bá a yín, yóò sì pa yín run, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe rere fún un yín tan.” 21Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ fún Joṣua pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! A yàn láti sin Olúwa.” 22Lẹ́yìn náà ni Joṣua wí pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín pé, ẹ ti yàn láti sin Olúwa.” Wọ́n dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí.” 23Nígbà náà ni Joṣua dáhùn wí pé, “Ẹ mú òrìṣà orílẹ̀-èdè mìíràn tí ń bẹ ní àárín yín kúrò, ki ẹ sì yí ọkàn yín padà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.