Joṣua 23:16
Joshua 23:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”
Joshua 23:16 in English
Joshua 23:16 · Berean Standard Bible
If you transgress the covenant of the LORD your God, which He commanded you, and go and serve other gods and bow down to them, then the anger of the LORD will burn against you, and you will quickly perish from this good land He has given you.”
Context
14“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. 15Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín. 16Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.