Joṣua 23:15
Joshua 23:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.
Joshua 23:15 in English
Joshua 23:15 · Berean Standard Bible
But just as every good thing the LORD your God promised you has come to pass, likewise the LORD will bring upon you the calamity He has threatened, until He has destroyed you from this good land He has given you.
Context
13Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín. 14“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. 15Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín. 16Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.