Joṣua 23:13
Joshua 23:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín.
Joshua 23:13 in English
Joshua 23:13 · Berean Standard Bible
know for sure that the LORD your God will no longer drive out these nations before you. Instead, they will become for you a snare and a trap, a scourge in your sides and thorns in your eyes, until you perish from this good land that the LORD your God has given you.
Context
11Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣọ́ra gidigidi láti fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run yín. 12“Ṣùgbọ́n bí ẹ bá yí padà, tí ẹ sì gba ìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù láàrín yín, tí ẹ sì ń fọmọ fún ara yín ní ìyàwó, tí ẹ sì bá wọn ní àjọṣepọ̀. 13Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé Olúwa Ọlọ́run yín kì yóò lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde mọ́ kúrò níwájú yín. Dípò èyí, wọn yóò jẹ́ ìkẹ́kùn àti tàkúté fún un yín, pàṣán ní ẹ̀yin yín àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ ó fi ṣègbé kúrò ní ilẹ̀ dáradára yí, èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fi fún yín. 14“Nísinsin yìí èmi ti fẹ́ máa lọ sí ibi tí àwọn àgbà ń rè. Ẹ mọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín àti àyà yín pé, kò sí ohun kan tí ó kùnà nínú àwọn ìlérí rere gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín. Gbogbo ìlérí tó ti ṣe kò sí ọ̀kan tí ó kùnà. 15Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.