Native Bible

Joshua 13:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé,

Joshua 13:15 in English

Joshua 13:15 · Berean Standard Bible

This is what Moses had given to the clans of the tribe of Reuben:

Context

13Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí. 14Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn. 15Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé, 16láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba 17sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.