Native Bible

Joshua 10:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì.

Joshua 10:9 in English

Joshua 10:9 · Berean Standard Bible

After marching all night from Gilgal, Joshua caught them by surprise.

Context

7Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 8Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.” 9Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì. 10Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda. 11Bí wọ́n sì tí ń sá ní iwájú Israẹli ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ọ̀nà láti Beti-Horoni títí dé Aseka, Olúwa rọ yìnyín ńlá sí wọn láti ọ̀run wá, àwọn tí ó ti ipa yìnyín kú sì pọ̀ ju àwọn tí àwọn ará Israẹli fi idà pa lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.