Native Bible

Joshua 10:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.”

Joshua 10:8 in English

Joshua 10:8 · Berean Standard Bible

The LORD said to Joshua, “Do not be afraid of them, for I have delivered them into your hand. Not one of them shall stand against you.”

Context

6Àwọn ará Gibeoni sì ránṣẹ́ sí Joṣua ní ibùdó ní Gilgali pé, “Ẹ má ṣe fi ìránṣẹ́ yín sílẹ̀. Ẹ gòkè tọ̀ wà wá ní kánkán kí ẹ sì gbà wá là. Ẹ ràn wá lọ́wọ́, nítorí gbogbo àwọn ọba Amori tí ń gbé ní orílẹ̀-èdè òkè dojú ìjà kọ wá.” 7Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gòkè lọ láti Gilgali pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, àti akọni nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 8Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Má ṣe bẹ̀rù wọn, Mo ti fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn ti yóò lè dojúkọ ọ́.” 9Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti wọ́de ogun ní gbogbo òru náà láti Gilgali, Joṣua sì yọ sí wọn lójijì. 10Olúwa mú kí wọn dààmú níwájú àwọn Israẹli, wọ́n sì pa wọ́n ní ìpakúpa ní Gibeoni. Israẹli sì lépa wọn ní ọ̀nà tí ó lọ sí Beti-Horoni, ó sì pa wọ́n dé Aseka, àti Makkeda.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.