Native Bible

Joshua 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda,

Joshua 10:16 in English

Joshua 10:16 · Berean Standard Bible

Now the five kings had fled and hidden in the cave at Makkedah.

Context

14Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí Olúwa gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú Olúwa jà fún Israẹli! 15Nígbà náà ni Joṣua àti gbogbo Israẹli padà sí ibùdó ní Gilgali. 16Ní báyìí àwọn ọba Amori márùn-ún ti sálọ, wọ́n sì fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta kan ní Makkeda, 17nígbà tí wọ́n sọ fún Joṣua pé, a ti rí àwọn ọba márààrún, ti ó fi ara pamọ́ nínú ihò àpáta ní Makkeda, 18ó sì wí pé, “Ẹ yí òkúta ńlá dí ẹnu ihò àpáta náà, kí ẹ sì yan àwọn ọkùnrin sí ibẹ̀ láti ṣọ́ ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.