Joẹli 3:20
Joel 3:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé, àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran.
Joel 3:20 in English
Joel 3:20 · Berean Standard Bible
But Judah will be inhabited forever, and Jerusalem from generation to generation.
Context
18“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀,
àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà;
gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi.
Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá,
yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu. 19Ṣùgbọ́n Ejibiti yóò di ahoro,
Edomu yóò sì di aṣálẹ̀ ahoro,
nítorí ìwà ipá tí a hù sì àwọn ọmọ Juda,
ní ilẹ̀ ẹni tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀. 20Ṣùgbọ́n Juda yóò jẹ́ ibùgbé títí láé,
àti Jerusalẹmu láti ìran dé ìran. 21Nítorí èmi yóò wẹ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ wọn nù, tí èmi kò tí ì wẹ̀nù.
Nítorí Olúwa ń gbé Sioni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.