Joẹli 2:9
Joel 2:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú; wọn yóò súré lórí odi, wọn yóò gùn orí ilé; wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè.
Joel 2:9 in English
Joel 2:9 · Berean Standard Bible
They storm the city; they run along the wall; they climb into houses, entering through windows like thieves.
Context
7Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára;
wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun;
olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀,
wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn. 8Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀;
olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀,
nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà
wọn kì yóò gbọgbẹ́. 9Wọn yóò sáré síwá sẹ́yìn ní ìlú;
wọn yóò súré lórí odi,
wọn yóò gùn orí ilé;
wọn yóò gbà ojú fèrèsé wọ̀ inú ilé bí olè. 10Ayé yóò mì níwájú wọn;
àwọn ọ̀run yóò wárìrì;
oòrùn àti òṣùpá yóò ṣókùnkùn,
àwọn ìràwọ̀ yóò sì fà ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn. 11Olúwa yóò sì bú ramúramù
jáde níwájú ogun rẹ̀:
nítorí ibùdó rẹ̀ tóbi gidigidi;
nítorí alágbára ní òun, tí n mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
nítorí ọjọ́ Olúwa tóbi ó sì ní ẹ̀rù gidigidi;
ara ta ni ó lè gbà á?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.