Joẹli 2:4
Joel 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.
Joel 2:4 in English
Joel 2:4 · Berean Standard Bible
Their appearance is like that of horses, and they gallop like swift steeds.*
Context
2Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀,
ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri.
Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá:
àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé,
ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí,
bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran. 3Iná ń jó níwájú wọ́n;
ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn.
Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn,
àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù;
nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn. 4Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin;
wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun. 5Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni
wọn ń fo ní orí òkè
bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ,
bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun. 6Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀:
gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.